Jump to content

Onome Akinbode-James

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Onome Akinbode-James
No. Mẹ́rìnlélógún – Duke Blue Devils
PositionIwájú àti Àárín
LeagueAtlantic Coast Conference
Personal information
BornỌjọ́ kẹ̀sán Osù kẹta Ọdún 2000
Abeokuta
NationalityNigerian
Listed height6 ft 3 in (1.91 m)
Career information
High schoolBlair Academy
CollegeDuke (2018–present)

Onome Akinbode-James tí a bí ní Ọjọ́ kẹ̀sán Osù kẹta Ọdún 2000 jẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfọwọ́gbá sínú agbọ̀n ti orílẹ̀-ède Nàìjíríà. Ó ṣojú orílẹ̀-ède Nàìjíríà ní bi FIBA Africa Under-16 Championship fún àwọn Obìrin . Ó gbá bọ́ọ̀lù aláfọwọ́gbá sínú agbọ̀n ti ilé ẹkọ́ girama fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù aláfọwọ́gbá sínú agbọ̀n ti obìnrin ti Duke Blue Devils .

Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Onome ní Ọjọ́ kẹ̀sán Osù kẹta Ọdún 2000 ní ìlú Abẹ́òkúta, ní ìpínlẹ̀ Ogun, gúsù iwọ̀ oòrùn orílẹ̀-ède Nàìjíríà . Ó ka ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta . Ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí gbá bọ́ọ̀lù aláfọwọ́gbá sínú agbọ̀n ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlá. Ó gba gbígbé lọ sí Blair Academy ní Blairstown, New Jersey, níbití ó ti parí ètò-ẹ̀kọ́ ilé-ìwé gíga rẹ̀.

Iṣẹ́ tí ó yàn láàyò ní Ilé-ìwé gíga

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n gba Onome sí iṣẹ́ ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Blair lẹ́yìn ìdíje FIBA Africa Under-16 Championship fún àwọn obìrin . Nígbà tí ó wá ní ọdún àgba rẹ̀, ó gba àmì mẹ́tàlá, àwọn àtúnṣe mọ́kànlá ó lé mẹ́jọ, àti àwọn ìdíwọ́ méjì ó lé méjì fún eré kọ̀ọ̀kan.

Onome sọ ọ̀rọ TED ní ilé-ìwé gíga Blair Academy lásìkò tí ó wà ní ọdún àgba rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà ni àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Africa, Country or Continent: The Broken Perception.

Iṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Onome bẹ̀rẹ isẹ́ ní Duke Blue Devils nípasẹ̀ olùkọ́ni àgbà Duke tẹ́lẹ̀ Joanne P. McCallie . Ní àkókó tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ó ní àròpin àmì mẹ́rin àti ìdíwọ́ máàrún ó lé méje fún eré kọ̀ọ̀kan.

Iṣẹ́ ẹgbẹ́ òkè- òkun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Onome ṣe aṣojú orílẹ̀-ède Nàìjíríà nínú ìdíje FIBA Africa Under-16 Championship fún àwọn obìnrin níbití ó ti ní àròpin àmi máàrún ó lé méje, àti àwọn ìdíwọ́ mẹ́wa ó lé mẹ́ta àti ìrànlọ́wọ́ ẹyọ̀kan dín díẹ̀ fún eré kan ní àkókò ìdíje náà. Ẹgbẹ́ Nàìjíríà gba àmì ẹ̀yẹ fàdákà lẹ́yìn ìjákulẹ̀ méjìdínlọ́gọ́ta sí mẹ́rìndínláàádọ́ta sí Mali ní Ìkẹyìn, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ tóótun sí ìdíje U-17 ti Àgbáyé fún Àwọn Obìnrin . Nàìjíríà kò kópa nínú ìdíje náà.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]