Harira
Harira | |
Type | Soup |
---|---|
Region or state | |
Main ingredients | Flour, tomatoes, lentils, chickpeas, onions, rice, meat (beef, lamb, or chicken), olive oil |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
Harira (al-ḥarīra) jẹ́ ọbẹ̀ ìbílẹ̀ Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà tí a sè ní Morocco[1] àti Algeria.[2][3][4] Algerian harira yàtọ̀ sí ti Moroccan harira níbi pé Algerian harira kò ní lentils. Ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n ó tún máa ń jẹ́ jíjẹ lásán gẹ́gẹ́ bí ìpanu. Ìyàtọ̀ púpọ̀ wà ó sì sábàá máa ń jẹ́ jíjẹ ní àsìkò Ramadan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè di ṣíṣe kárí ọdún.
Ó tún jẹ́ ara oúnjẹ Maghrebi cuisine, níbi tí júìsì àti ẹyin ti máa ń di fífi síi láti lè fi kún adùn ọbẹ̀ náà. Gẹ́gẹ́ bí àwọn Mùsùlùmí, tí wọ́n máa ń jẹ ọbẹ̀ náà fún oúnjẹ ìsínu Iftar, Jews máa ń sínu pẹ̀lú rẹ̀ lásìkò Yom Kippur.[5]
Gẹ́gẹ́ bí àwọn onítàn oúnjẹ Jewish ti sọ Gil Marks, Harira ṣẹ̀ wá láti Al-Andalus.[6]
Sísè
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ohun èlò Harira kún fún àwọn èròjà wọ̀nyí, ó sì lè yàtọ̀, ó dá lórí àwọn agbègbè:
- Tadouira - àpòpọ̀ tó ki tí a ṣe láti ara fáwà àti omi àti nígbà mìíràn pẹ̀lú tìmátí alágolo, èyí tí wọ́n máa ń fi sí i ní ìparí ṣíṣè rẹ̀.[7]
- Tìmátí àti tomato concentrate
- Lentils
- Adìẹ
- Ẹ̀wà
- Àlùbọ́sà
- Ìrẹsì
- Ẹyin
- Ẹran díẹ̀: (beef, lamb tàbí adìẹ)
- Síbí kan tàbí méjì ti olive oil.
Ẹran náà , tí ó sábàá máa ń jẹ́ ọ̀yà, máa ń di ṣíṣè pẹ̀lú cinnamon, ginger, turmeric tàbí àwọ̀ mìíràn bíi saffron, àti àgbo tuntun bíi cilantro àti parsley.[8]
Lemon juice náà lè di fífi kún un nígbà jíjẹ. Ọbẹ̀ náà máa ń dára jù tí èèyàn bá fi sílẹ̀ mọ́jú.[9]
Ó sábàá máa ń di jíjẹ pẹ̀lú ẹyin ṣíṣè tí wọ́n fi iyọ̀ ra àti cumin, dates àti àwọn ààyò èso gbígbẹ mìíràn bí figs, oyin ìbílẹ̀ àti àwọn búrẹ́dì tí a ṣe nílé tàbí pankéèkì.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ [1] collinsdictionary.com
- ↑ Ken Albala (2011). Food Cultures of the World Encyclopedia. ABC-CLIO. pp. 9. ISBN 978-0-313-37626-9. https://books.google.com/books?id=NTo6c_PJWRgC&pg=PA9.
- ↑ Bonn, Charles (1999). "Paysages littéraires algeriens des années 90 : TEMOIGNER D'UNE TRAGEDIE ?" (in en). Paysages littéraires algeriens des années 90: 1–188. https://www.torrossa.com/en/resources/an/5122317.
- ↑ El Briga, C. (1996-08-01). "Ennayer" (in fr). Encyclopédie berbère (17): 2643–2644. doi:10.4000/encyclopedieberbere.2156. ISSN 1015-7344. https://journals.openedition.org/encyclopedieberbere/2156.
- ↑ "Recipe: How to make harira". Jewish Journal. 12 March 2015.
- ↑ Marks, Gil (2010-11-17) (in en). Encyclopedia of Jewish Food. HMH. ISBN 978-0-544-18631-6. https://books.google.com/books?id=gFK_yx7Ps7cC&q=harira is a thick.
- ↑ "Tadouira" (in fr). Cuisine Marocaine. http://www.cuisinedumaroc.com/lexique-culinaire-marocain/tadouira/.
- ↑ "Classic Moroccan Harira: Tomato, Lentil, and Chickpea Soup". The Spruce Eats.
- ↑ "Harira Soup". The New York Times.