Chess
ChessSet.jpg |
}}
Ayò Chess jẹ́ ayò tí a ma ń ta lórí tábìlì lábẹ́lé láàrín ònta ènìyàn méjì. Ònta kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ma dá ayo wọn mọ̀ pẹ̀lú kí ìkan apá ilé kan dúdú kí ìkejì sì funfun. Àwọn ònta wọ̀nyí ni wọn yóò ma darí àwọn ayò tí wọ́n jẹ́ ikọ̀ ọmọ ogun ilé kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń pè ní chess pieces. Gbogbo ète àti èrò ònta kọ̀ọ̀kan ni kí ó fi ikọ̀ ọmọ ogun ayò tirẹ̀ pa ẹnìkejì rẹ̀ láyò tí wọ́n ń pè ní checkmate. Ṣáájú kí èyí tó wáyé, wọ́n gbọ̀dọ̀ dé tàbí pa Ọba tí ó jẹ́ olórí. Ibi tí ayò yí ti ṣẹ̀wá ni agbègbè chaturanga, tí ó wà ní ibi tí ó di orílẹ̀-èdè India lóní ní nkan bí ọ̀rùndún karùn ún sẹ́yìn. Àmọ́ òfin àti ìlànà títa ayò náà tí a ń ló títí di òní ni wọ́n gbé kalẹ̀ ní Yúróòpù ní nkan ní ọ̀rùndún keje sẹ́yìn tí gbogbo ayé sì tẹ́wọ́ gba òfin ati ìlànà yí títí di ìparí ọ̀rùndún kọkàndínlógún . Lóní, Chess jẹ́ ayò tí ó gbajú-gbajà jùlọ káàkiri àgbáyé tí ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn sì ń fi ayò náà ṣeré ọpọlọ.
Ayò Chess jẹ́ ayò tí a ń fi ọgbọ́n inú ta tí ó sì nííṣe pẹ̀lú ìlànà tó mọ́yánlórí tí kò sì ní ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí kankan. Lórí àyà ayò ni a ti ma ń rí àwọn ọmọ ayò tí wọ́n jẹ́ mẹ́rìndínlógún ní apá ikọ̀ kọ̀ọ̀kan ma ń tó ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní ìwọ̀n 8×8. Ònta kọ̀ọ̀kan ma ń darí ọmọ ayò mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ń pè ní Chess piece. Nínú àwọn ọmọ ayò yí ni a ti ma ń rí Ọba, Olorì, róòkù méjì, báàọ́ọ́bù méjì, náìtì méjì, àti àwọn ọmọ ogun kékèké mẹ́jọ tí wọ́n ń pè ní pawns. Nínú ìlànà títa ayò yí, ònta tí ó bá mú ikọ̀ funfun ni yóò kọ́kó bẹ̀rẹ̀ títa ayò kí ònta kejì tí ó mú ikọ̀ ọmọ ogun dúdú ó tó ta tẹ̀le. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ònta méjèjì yí ní ó lè pa Ọba pẹ̀lú dídẹ pàkúté láti fi pa Ọba ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ lójú ọpọ́n. Ayò yí lè pari pẹ̀lú pípa ọba tàbí kí wọ́n ta ọ̀mì níparí ìdíje ayò.
Gbígbé ìdíje ayò Chess kalẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ ní àárín ọ̀rùndún kọkàndínlógún nígbà tí àjọ FIDE (the International Chess Federation) ń ṣe àbójútó ìdíje eré ìdárayá yí. Ẹni akọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ gba adé World Chess Champion, ni Wilhelm Steinitz ní ọdún 1886; nígbà tí ẹni tí ó di amì-ẹ̀yẹ náà mú lọ́wọ́ báyi ni Ding Liren. Orísiríṣi àjọ ni wọ́n ti gbérasọ láti ma ṣe agbátẹrù fún ìdíje eré ìdárayá Chess lágbàáyé, àwọn ènìyàn kan rí eré ìdárayá Chess gẹ́gẹ́ bí ọnà, ọ̀nà yí ni kò tún dúró lásán tí ó jàsí wípé ò nííṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ bíi: mathematics, computer science, àti psychology.
Lára àfojúsùn àwọn òníọ̀ sayẹ́nsì láyé àtijọ́ ni kí wọ́n ṣẹ̀dá kọ̀mpútà tí yóò ma ta ayò Chess (chess-playing machine). Ní ọdún 1997, Deep Blue ni ó jẹ́ kọ̀mpútà akọ́kó tí yóò gbadé ẹni tí ó mọ ayò chess ta jùlọ lágbàáyé nígbà tí ó fẹ̀yìn alátakò rẹ̀ Garry Kasparov tí òun náà jẹ́ kọ̀pútà gbolẹ̀. Láyé òde òní, ẹ̀rọ kọ̀mpútà ti di agbaọ̀jẹ̀ nínú kí á ta ayò Chess ju ọmọnìyàn lọ lágbàáyé. Èyí náà sì mú ìdàgbà-sókè bá ìlànà, agbékalẹ̀, títa ayò náà lágbàáyé. Àdàkọ:AN chess
Àwọn òfin rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ofin ati ìlànà tí ó de títa ayò yí ni àjọ FIDE (Fédération Internationale des Échecs; "International Chess Federation"), tí wọ́n ṣe agbátẹrù fún eré ìdárayá yí lágbàáyé ti gbé kalẹ̀ nínú ìwé kan tí wọ́n pe ní Handbook.[1] Òfin yí ni wọ́n tún tari síta tí wọ́n sì tún ṣe àtúnyẹ̀wò rẹ̀ ní ọdún 2023.
Àtòpọ̀ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Chess sets Èyí wá ní Àrà oríṣiríṣi : fún ìdíje, Staunton Chess Set ní ìlànà tí a máa ṣàmúlò rẹ̀ tàbí lò. Ọ̀nà méjì ní a máa ń gbà dá àwọn ọmọ inú Chess mọ ní wíwọ onírúurú èyí tí ó jẹ́ tàbí àwọ̀; èyí ní àwọ̀ funfun àti àwọ̀ dúdú, tí a tún lè pé ní Ṣẹ́ẹ̀sì Aláwọ̀ Dúdú àti funfun. Àwọn ẹni tí wọn ń tá Chess ni alè lé ní olúta Ṣẹ́ẹ̀sì tàbí aláyò, bákan náà ní àwon Ọmọ inú Ṣẹ́ẹ̀sì jẹ́ funfun tàbí dúdú. Tí Sẹ́ẹ̀tì Sẹ́ẹ̀sì jẹ́ mẹ́rìndínlógún tí àwọn ọmọ inú rẹ sí jẹ: Ọba kan, Olórí kan, Rúùkù méjì, Bíṣọ́bù méjì, Knight méjì, àti Pawns mẹ́jọ.
A máa ń ta ayo ṣẹ́ẹ̀sì lórí pákó onígun Mẹ́rin tí ó ní Row Méjọ, Column mẹ́jọ. Nípa àpéjọpọ̀, àwọn onigun mẹrin tí ojú líla rẹ jẹ́ mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ní àwọ̀ oríṣi méjì tí ó jẹ́ Funfun àti Dúdú; àwọn àwọ̀ tí ó wọ́pọ̀ fún Ayò Ṣẹ́ẹ̀sì jẹ́ funfun àti brown, tàbí funfun àti àwọ̀ ewé.
Àwọn ọmọ inú ayò Ṣẹ́ẹ̀sì ni ó wà ní ojú àwòrán yìí ní òkè. Amò láti ipò kíní tí ó jẹ́ àwọ̀ Funfun, láti apá òsì dé ọ̀tún: àwọn ọmọ náà sì ni: Rook, Knight, Bíṣọ́bù, Olorì, Ọba, Bíṣọ́bù, Knight àti Rook. Pawn méjọ ní o wà ní ipò Kejì. Àwọn àwọ̀ dúdú sí wà ní òdìkejì bí àti to fúnfún, tí ó sí jẹ́ ìkanáà . Pákó Sẹ́ẹ̀sì náà wà ní apá òtún tí ó súnmọ́ ọwọ́ Aláyò. Ipò tí Ọba àti Olorí gbọ́dọ̀ wà ìbamu pẹlú ọ̀rọ̀ kàn tí wọn máa ǹ so pé "Olorì lórí aye rẹ̀", tí ó túmọ̀ sí pé Olorì funfun lori àwọ̀ funfun, Olorì dúdú lórí àwọ̀ dúdú).
Nínú ìdíje, àwọn Olùsètò ìdíje ní wọn yóò fún àwọn Olùdíje ní ọmọ ayò Ṣẹ́ẹ̀sì; tí ó bá jẹ́ fún ìdárayá lásán, àwọn olùta a máa lo sísọ Coin sókè, tàbí kí wọn fí pawn dudu àti fúnfún sí ọwọ́ méjẹ̀jjì kí àwọn olùta mú ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, èyí tí oníkálukú bá mú ní wọn yóò fi ta ayò náà.
Bí a ṣe ń gbé ayò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Funfun ni yó kókó gbéra, lẹyìn tí àwọn ìyókù ó sì tẹ̀le, wọ́n sì ma n gbéra ní kọ̀kan. Àwọn tí ó ta ayò yìí le gbé ayò náà sí ojúgun tí ayò míràn kò sí tàbí ibi tí ayò olùtakò wà, eléyìí á sì mú kí a yọ ayò náà kúrò. Kí kúrò láti ojúgun kan sí òmíràn ṣe pàtàkì; ẹni tí ó tayò gbọ́dọ̀ gbé ọkàn lára àwọn ayò rẹ̀ síbò míràn lẹ́yìn tí olùtakò rẹ̀ tí gbé ayò.
Oríṣiríṣi ayò ní bí wọ́n ṣe ma ń gbe.
- Ọba le lọ sí ojúgun tí ó bá fẹ́. Ọba jẹ́ ayò tí ó lágbára jù, ó sì ṣe pàtàkì fún olùtakò láti ṣa ipa láti yọ oba alátakò rẹ̀ nínú eré, èyí le mú kí ó jáwé olúborí nínú eré ayò náà. Check and checkmate below).
- Rook le lọ ibi tí ó fé ṣùgbọ́n kò le gba orí ayò míràn kọjá.
- Bishop náà le lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúgun tí ó fé nípa lílo sọ́tún sọ́sì ṣùgbọ́n kò le gba orí àwọn ayò míràn kọjá.
- Queen ní le ṣe àwọn nkan tí rook àti bishop le se ṣùgbọ́n kò le gba orí àwọn ayò míràn kọjá.
- A Knight le lọ ojúgun tí ó sún mọ́ sì, òun nìkan sì ni ayò tí ó le gba orí ayò míràn kọjá.
- Pawn náà le lọ sí ojúgun míràn tí ayò kò si.
Pípa ọmọ ayò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nígbà tí ọba bá wà ní inú ewu, wọn á sọ wípé Check. Ọ̀nà tí ọba lè gbà bọ́ lọ́wọ́ ewu ni kí ó ó kúrò ní ojú ibi tí ó wà kí ẹ̀mí rẹ̀ lè dè. Ọ̀nà mẹ́ta ni wọ́n lè gbà bò lọ́wọ́ ewu kí ó sì jà padà. check. A move in response to a check is legal only if it results in a position where the king is no longer in check. There are three ways to counter a check:
- Capture the checking piece.
- Interpose a piece between the checking piece and the king (which is possible only if the attacking piece is a queen, rook, or bishop and there is a square between it and the king).
- Move the king to a square where it is not under attack.
Castling is not a permissible response to a check.[1]
The object of the game is to checkmate the opponent; this occurs when the opponent's king is in check, and there is no legal way to get it out of check. It is never legal for a player to make a move that puts or leaves the player's own king in check. In casual games, it is common to announce "check" when putting the opponent's king in check, but this is not required by the rules of chess and is usually not done in tournaments.[2]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "Fide Laws of Chess taking effect from 1 January 2023". FIDE. Archived from the original on 1 January 2023. Retrieved 1 January 2023. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ United States Chess Federation. (2003). U.S. Chess Federation's official rules of chess. Just, Tim., Burg, Daniel B. (5th ed.). New York. ISBN 0-8129-3559-4. OCLC 52886322.