Ìlú Bàsà
Bassa | |
---|---|
Coordinates: 7°54′N 7°03′E / 7.900°N 7.050°ECoordinates: 7°54′N 7°03′E / 7.900°N 7.050°E | |
Country | Nigeria |
State | Ìpínlẹ̀ Kogí |
Headquarters | Oguma |
Area | |
• Total | 1,925 km2 (743 sq mi) |
Population (2006 census) | |
• Total | 139,993 |
Time zone | UTC 1 (WAT) |
3-digit postal code prefix | 272 |
ISO 3166 code | NG.KO.BA |
Bassa jẹ́ ìlú kan tí ó wà ní abẹ́ akóso Ìjọba Ìbílẹ̀ Ogunma ní Ìpínlẹ̀ Kogí, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìlú yí pààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Benue ní apá gúsù, ó pààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Niger ní apá ìwọ̀-Oòrùn.
Ìlú Bàsà ní ìlẹ̀ tí ó tó 1,925 km2 níye, wọ́n sì ní àwọn olùgbé tí wọ́n ń gbé níbẹ̀ 139,993 gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn ọdún 2006 ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀[1] Nígbà tí yóò fi di ọdún 2016, àwọn olùgbé ibẹ̀ ti tó 188,600 ń iye.[2]
Bassa-nge ni àwọn abúlé bíi : Gboloko, Ajigido, Kpata àti Ecewu wà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀.
Ìlà-ìpè agbègbè Bàsà ni 272.[3]
Ìjọba ìbílẹ̀ Bàsà ní Ìpínlẹ̀ Kogí ni ó kan fún àwọn ẹ̀ka ẹ̀yà mẹ́ta pondoro. Akọ́kọ́ ni Bassa-komo, Bassa-nge àti Egbira koto. Bassa-Komo ni ó ní àwọn olùgbé tó pọ̀ jùlọ, nígbà tí Bàsà-Nge, tí Egbira Koto ń tẹ̀lé wọn lénje-lénje. Ẹni tí ó jẹ́ aṣíwájú àti olùdarí awọn ẹ̀yà Bàsà-Komo ni wọ́n ń pè ní AGUMA , nígba tí Etsu" jẹ́ olùdarí ati aláṣẹ fún Bassa-Nge tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ọba kọ́kọ́ tó lààmì-laaka, bẹ́ẹ̀ naa ni "OHIOGBA" ti Mozum jẹ́ ọ̀ba tí ó wà ní ipò kẹ́ta nínú àwọn ọba Egbira.
Ẹni tí ó jẹ́ ọba ati aláṣẹ àwọn ẹ̀yà Bassa Nge ni wọ́n mọ̀ sí Etsu Bassa Nge, ààfin rẹ̀ ni ó wà ní ìlú Gboloko tí ó jẹ́ olú-ìlú fún àwọn ẹ̀yà Bassa Nge.
Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ẹ̀yà Bassa-Nge
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ẹ̀yà Bassa-Nge ni a lè tan orí fún wọn de ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà Nupe. Ìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwọn ẹ̀yà Bàsà Nge ni wọ́n fìgbà kan jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà Núpé, nítorí èdè àti àṣà kan náà tí wọ́n jọ ní, ìdí ni wípé púpọ̀ nínú àwọn tí wọ́n sa fún ogun àwọn Fúlàní ni wọ́n lọ tẹ̀dó sí àwọn ìlú bíi: Ìlọrin ní Ìpínlẹ̀ Kwara àti etí odo ọya ní Ìpínlẹ̀ Benue.
Àwọn Itọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ HASC, population, area and Headquarters Statoids
- ↑ "Kogi (State, Nigeria) - Population Statistics, Charts, Map and Location". www.citypopulation.de (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-09-18.
- ↑ "Post Offices- with map of LGA". NIPOST. Archived from the original on 7 October 2009. Retrieved 2009-10-20. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)